Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 2:4-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitori ti Oluwa rán mi si Jeriko. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn de Jeriko.

5. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Jeriko tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́.

6. Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ.

7. Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani.

8. Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ.

9. O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi.

10. On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃.

11. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, ti nwọn nsọ̀rọ, si kiyesi i, kẹkẹ́ iná ati ẹṣin iná si là ãrin awọn mejeji; Elijah si ba ãjà gòke re ọrun.

12. Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On kò si ri i mọ: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji.

13. On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si pada sẹhin, o si duro ni bèbe Jordani.

14. On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun Elijah wà? Nigbati on pẹlu si lù omi na, nwọn si pinyà sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja.

15. Awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Jeriko nihà keji si ri i, nwọn si wipe, Ẹmi Elijah bà le Eliṣa. Nwọn si wá ipade rẹ̀; nwọn si tẹ̀ ara wọn ba silẹ niwaju rẹ̀.

16. Nwọn si wi fun u pe, Wò o na, ãdọta ọkunrin alagbara mbẹ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ; awa bẹ̀ ọ, jẹ ki nwọn ki o lọ, ki nwọn ki o si wá oluwa rẹ lọ: bọya Ẹmi Oluwa ti gbé e sokè, o si ti sọ ọ sori ọkan ninu òke nla wọnni, tabi sinu afonifojì kan. On si wipe, Ẹ máṣe ranṣẹ.

17. Nigbati nwọn si rọ̀ ọ titi oju fi tì i, o wi fun wọn pe, Ranṣẹ. Nitorina nwọn rán ãdọta ọkunrin, nwọn si wá a ni ijọ mẹta, ṣugbọn nwọn kò ri i.

18. Nwọn si tun pada tọ̀ ọ wá, (nitori ni Jeriko li o joko,) o wi fun wọn pe, Emi kò ti wi fun nyin pe, Ẹ máṣe lọ?

19. Awọn ọkunrin ilu na si wi fun Eliṣa pe, Kiyesi i, itẹ̀do ilu yi dara, bi oluwa mi ti ri i: ṣugbọn omi buru, ilẹ si ṣá.

20. On si wipe, Mu àwokóto titun kan fun mi wá, si fi iyọ̀ sinu rẹ̀; nwọn si mu u tọ̀ ọ wá.

21. On si jade lọ si ibi orisun omi na, o si dà iyọ na sibẹ, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ṣe àwotan omi wọnyi; lati ihin lọ, kì yio si ikú mọ, tabi aṣálẹ.

22. Bẹ̃ni a ṣe àwotan omi na titi di oni oloni, gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa ti o sọ.

23. O si gòke lati ibẹ lọ si Beteli: bi o si ti ngòke lọ li ọ̀na, awọn ọmọ kekeke jade lati ilu wá, nwọn si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si wi fun u pe, Gòke lọ, apari! gòke lọ, apari!