Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 13:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ati iyokù iṣe Jehoahasi, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

9. Jehoahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i ni Samaria: Joaṣi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

10. Li ọdun kẹtadilogoji Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ọdun mẹrindilogun.

11. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa; on kò lọ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: ṣugbọn o rìn ninu wọn.

12. Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi ba Amasiah ọba Juda jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

13. Joaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Jeroboamu si joko lori itẹ́ rẹ̀: a si sìn Joaṣi ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli.

14. Eliṣa si ṣe aisàn ninu eyi ti kò ni yè, Joaṣi ọba Israeli si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, o si sọkun si i li oju, o si wipe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀!

15. Eliṣa si wi fun u pe, Mu ọrun pẹlu ọfà: on si mu ọrun ati ọfà.

16. O si wi fun ọba Israeli pe, Fi ọwọ rẹ le ọrun na: on si fi ọwọ rẹ̀ le e: Eliṣa si fi ọwọ tirẹ̀ le ọwọ ọba.

17. O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn.

18. O si wipe, Kó awọn ọfà na. O si kó wọn. O si wi fun ọba Israeli pe, Ta si ilẹ. On si ta lẹrinmẹta, o si mu ọwọ duro.