Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 5:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si ṣe, nigbati ọba Israeli kà iwe na tan, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Emi ha iṣe Ọlọrun, lati pa ati lati sọ di ãyè, ti eleyi fi ranṣẹ si mi lati ṣe awòtan enia kan kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀? nitorina, ẹ rò o wò, mo bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò o bi on ti nwá mi ni ijà.

8. O si ṣe, nigbati Eliṣa enia Ọlọrun gbọ́ pe, ọba Israeli fà aṣọ rẹ̀ ya, o si ranṣẹ si ọba wipe, Ẽṣe ti iwọ fi fà aṣọ rẹ ya? jẹ ki o tọ̀ mi wá nisisiyi, on o si mọ̀ pe, woli kan mbẹ ni Israeli.

9. Bẹ̃ni Naamani de pẹlu awọn ẹṣin rẹ̀ ati pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀, o si duro li ẹnu-ọ̀na ile Eliṣa.

10. Eliṣa si ràn iranṣẹ kan si i wipe, Lọ, ki o si wẹ̀ ni Jordani nigba meje, ẹran-ara rẹ yio si tun bọ̀ sipò fun ọ, iwọ o si mọ́.

11. Ṣugbọn Naamani binu, o si pada lọ, o si wipe, Kiyesi, i, mo rò ninu mi pe, dajudaju on o jade tọ̀ mi wá, yio si duro, yio si kepè orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, yio si fi ọwọ rẹ̀ pa ibẹ̀ na, yio si ṣe awòtan ẹ̀tẹ na.

12. Abana ati Farpari, awọn odò Damasku kò ha dara jù gbogbo awọn omi Israeli lọ? emi kì iwẹ̀ ninu wọn ki emi si mọ́? Bẹ̃li o yipada, o si jade lọ ni irúnu.

13. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sunmọ ọ, nwọn si ba a sọ̀rọ, nwọn si wipe, Baba mi, woli iba wi fun ọ pe, ki o ṣe ohun nla kan, iwọ kì ba ti ṣe e bi? melomelo, nigbati o wi fun ọ pe, Wẹ̀, ki o si mọ́?

14. Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́.

15. O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ.

16. Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀.

17. Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa.

18. Ninu nkan yi ni ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ, nigbati oluwa mi ba lọ si ile Rimmoni lati foribalẹ nibẹ, ti on ba si fi ara tì ọwọ mi, ti emi tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni: nigbati mo ba tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni, ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ ninu nkan yi.

19. On si wi fun u pe, Mã lọ ni alãfia. Bẹ̃ni o si jade lọ jinà diẹ kuro lọdọ rẹ̀.

20. Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀.