Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 24:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ọba Egipti kò si tun jade kuro ni ilẹ rẹ̀ mọ; nitori ọba Babeli ti gbà gbogbo eyiti iṣe ti ọba Egipti lati odò Egipti wá titi de odò Euferate.

8. Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Nehuṣta, ọmọbinrin Elnatani ti Jerusalemu.

9. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.

10. Li akokò na, awọn iranṣẹ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá si Jerusalemu, a si dotì ilu na.

11. Nebukadnessari ọba Babeli si de si ilu na, nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si dotì i.

12. Jehoiakini ọba Juda si jade tọ̀ ọba Babeli lọ, on, ati iya rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn iwẹfa rẹ̀: ọba Babeli si mu u li ọdun kẹjọ ijọba rẹ̀.

13. O si kó gbogbo iṣura ile Oluwa lọ kuro nibẹ, ati iṣura ile ọba, o si ké gbogbo ohun-èlo wura wẹwẹ ti Solomoni ọba Israeli ti ṣe ni tempili Oluwa, bi Oluwa ti sọ.

14. O si kó gbogbo Jerusalemu lọ, ati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo awọn alagbara akọni enia, ani ẹgbãrun igbèkun, ati gbogbo awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹ̀dẹ: kò kù ẹnikan, bikòṣe iru awọn ti o jẹ talakà ninu awọn enia ilẹ na.

15. O si mu Jehoiakini lọ si Babeli, ati iya ọba, ati awọn obinrin ọba, ati awọn iwẹ̀fa rẹ̀, ati awọn alagbara ilẹ na, awọn wọnyi li o kó ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli.

16. Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọla, ẹ̃dẹgbãrin, ati awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹdẹ ẹgbẹrun, gbogbo awọn ti o li agbara ti o si yẹ fun ogun, ani awọn li ọba Babeli kó ni igbèkun lọ si Babeli.

17. Ọba Babeli si fi Mattaniah arakunrin baba rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Sedekiah.

18. Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna.

19. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.

20. Nitori nipa ibinu Oluwa li o ṣẹ si Jerusalemu ati Juda, titi o fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀; Sedekiah si ṣọ̀tẹ si ọba Babeli.