Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 19:1-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bò ara rẹ̀, o si lọ sinu ile Oluwa.

2. O si rán Eliakimu, ti iṣe olori ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn àgba alufa, ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bò ara, sọdọ Isaiah woli ọmọ Amosi.

3. Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Ọjọ oni ọjọ wàhala ni, ati ti ibawi, ati ẹgàn: nitoriti awọn ọmọ de oju-ibí, kò si si agbara lati bi.

4. Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Rabṣake ẹniti ọba Assiria oluwa rẹ̀ ti rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè, yio si ba a wi nitori ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́: njẹ nitorina, gbé adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.

5. Bẹ̃li awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah.

6. Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ sọ fun oluwa nyin, Bayi li Oluwa wi pe, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọnni, ti o ti gbọ́, ti awọn iranṣẹ ọba Assiria fi sọ ọ̀rọ odi si mi.

7. Kiyesi i, emi o rán ẽmi kan si i, on o si gbọ́ ariwo, yio si pada si ilẹ on tikalarẹ̀; emi o si mu u ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.

8. Bẹ̃ni Rabṣake pada, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitoriti o ti gbọ́ pe o ti lọ kuro ni Lakiṣi.

9. Nigbati o si gburo Tirhaka ọba Etiopia, pe, Kiyesi i, o jade wá lati ba ọ jagun; o si tun rán awọn onṣẹ si ọdọ Hesekiah wipe,

10. Bayi li ẹnyin o sọ fun Hesekiah ọba Juda, wipe, Máṣe jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọwọ ọba Assiria.

11. Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si gbogbo ilẹ, ni pipa wọn run patapata: a o ha si gbà iwọ bi?

12. Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun; bi Gosani, ati Harani, ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti o wà ni Telassari?

13. Nibo li ọba Hamati, ati ọba Arpadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wà?

14. Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn onṣẹ na, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ sinu ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.

15. Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye.

16. Dẹti rẹ silẹ Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: ki o si gbọ́ ọ̀rọ Sennakeribu ti o rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè.

17. Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti pa awọn orilẹ-ède run ati ilẹ wọn.