Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 17:25-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. O si ṣe li atètekọ-gbé ibẹ wọn, nwọn kò bẹ̀ru Oluwa: nitorina ni Oluwa ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, ti o pa ninu wọn.

26. Nitorina ni nwọn ṣe sọ fun ọba Assiria wipe, Awọn orilẹ-ède ti iwọ ṣi kuro, ti o si fi sinu ilu Samaria wọnni, kò mọ̀ iṣe Ọ̀lọrun ilẹ na: nitorina li on ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, si kiyesi i, nwọn pa wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ iṣe Ọlọrun ilẹ na.

27. Nigbana li ọba Assiria paṣẹ, wipe, Ẹ mu ọkan ninu awọn alufa ti ẹnyin ti kó ti ọhún wá lọ sibẹ; ẹ si jẹ ki wọn ki o lọ igbe ibẹ, ki ẹ si jẹ ki o ma kọ́ wọn ni iṣe Ọlọrun ilẹ na.

28. Nigbana ni ọkan ninu awọn alufa ti nwọn ti kó ti Samaria lọ, wá, o si joko ni Beteli, o si kọ́ wọn bi nwọn o ti mã bẹ̀ru Oluwa.

29. Ṣugbọn olukuluku orilẹ-ède ṣe oriṣa tirẹ̀, nwọn si fi wọn sinu ile ibi giga wọnni ti awọn ara Samaria ti ṣe, olukuluku orilẹ-ède ninu ilu ti nwọn ngbe.

30. Awọn enia Babeli ṣe agọ awọn wundia, ati awọn enia Kuti ṣe oriṣa Nergali, ati awọn enia Hamati ṣe ti Aṣima,

31. Ati awọn ara Afa ṣe ti Nibhasi ati ti Tartaki, ati awọn ara Sefarfaimu sun awọn ọmọ wọn ninu iná fun Adrammeleki ati Anammeleki awọn òriṣa Sefarfaimu.

32. Nwọn bẹ̀ru Oluwa pẹlu, nwọn si ṣe alufa ibi giga wọnni fun ara wọn, ninu awọn enia lasan, ti nrubọ fun wọn ni ile ibi giga wọnni.

33. Nwọn bẹ̀ru Oluwa, nwọn si nsìn oriṣa wọn gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède, ti nwọn kó lati ibẹ lọ.

34. Titi di oni yi nwọn nṣe bi iṣe wọn atijọ: nwọn kò bẹ̀ru Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò ṣe bi idasilẹ wọn, tabi ilàna wọn, tabi ofin ati aṣẹ ti Oluwa pa fun awọn ọmọ Jakobu, ti o sọ ni Israeli;

35. Awọn ẹniti Oluwa ti ba dá majẹmu, ti o si ti kilọ fun wọn, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ tẹ̀ ara nyin ba fun wọn, tabi ki ẹ sìn wọn, tabi ki ẹ rubọ si wọn:

36. Ṣugbọn Oluwa ti o mu nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, pẹlu agbara nla ati ninà apá, on ni ki ẹ mã bẹ̀ru, on ni ki ẹ si mã tẹriba fun, on ni ki ẹ sì mã rubọ si.

37. Ati idasilẹ wọnni, ati ilàna wọnni, ati ofin ati aṣẹ ti o ti kọ fun nyin, li ẹnyin o mã kiyesi lati mã ṣe li ọjọ gbogbo; ẹnyin kò si gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miràn.

38. Ati majẹmu ti mo ti ba nyin dá ni ẹnyin kò gbọdọ gbàgbe; bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran.

39. Ṣugbọn Oluwa Ọlọrun nyin ni ẹnyin o mã bẹ̀ru; on ni yio si gbà nyin lọwọ awọn ọta nyin gbogbo.

40. Nwọn kò si gbọ́, ṣugbọn nwọn ṣe bi iṣe wọn atijọ.

41. Bẹ̃li awọn orilẹ-ède wọnyi bẹ̀ru Oluwa, ṣugbọn nwọn tun sin awọn ere fifin wọn pẹlu; awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ-ọmọ wọn, bi awọn baba wọn ti ṣe, bẹ̃li awọn na nṣe titi fi di oni yi.