Nitorina ni nwọn ṣe sọ fun ọba Assiria wipe, Awọn orilẹ-ède ti iwọ ṣi kuro, ti o si fi sinu ilu Samaria wọnni, kò mọ̀ iṣe Ọ̀lọrun ilẹ na: nitorina li on ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, si kiyesi i, nwọn pa wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ iṣe Ọlọrun ilẹ na.