Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 16:10-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ahasi ọba si lọ si Damasku lati pade Tiglat-pileseri, ọba Assiria, o si ri pẹpẹ kan ti o wà ni Damasku: Ahasi ọba si rán awòran pẹpẹ na, ati apẹrẹ rẹ̀ si Urijah alufa, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ ọnà rẹ̀.

11. Urijah alufa si ṣe pẹpẹ kan gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba fi ranṣẹ si i lati Damasku wá; bẹ̃ni Urijah alufa ṣe e de atibọ̀ Ahasi ọba lati Damasku wá.

12. Nigbati ọba si ti Damasku de, ọba si ri pẹpẹ na: ọba si sunmọ pẹpẹ na, o si rubọ lori rẹ̀.

13. O si sun ẹbọ ọrẹ-sisun rẹ̀ ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, o si ta ohun-mimu rẹ̀ silẹ, o si wọ́n ẹ̀jẹ ọrẹ-alafia rẹ̀ si ara pẹpẹ na.

14. Ṣugbọn o mu pẹpẹ idẹ ti o wà niwaju Oluwa kuro lati iwaju ile na, lati agbedemeji pẹpẹ na, ati ile Oluwa, o si fi i si apa ariwa pẹpẹ na.

15. Ahasi ọba si paṣẹ fun Urijah alufa, wipe, Lori pẹpẹ nla ni ki o mã sun ọrẹ-sisun orowurọ̀ ati ọrẹ-jijẹ alalẹ, ati ẹbọ-sisun ti ọba, ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, pẹlu ọrẹ-sisun ti gbogbo awọn enia ilẹ na, ati ọrẹ-jijẹ wọn, ati ọrẹ ohun-mimu wọn; ki o si wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ ọrẹ-sisun na lori rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀jẹ ẹbọ miran: ṣugbọn niti pẹpẹ idẹ na emi o mã gbero ohun ti emi o fi i ṣe.

16. Bayi ni Urijah alufa ṣe, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba pa li aṣẹ.

17. Ahasi ọba si ké alafo ọnà arin awọn ijoko na, o si ṣi agbada na kuro lara wọn; o si gbé agbada-nla na kalẹ kuro lara awọn malu idẹ ti mbẹ labẹ rẹ̀, o si gbé e kà ilẹ ti a fi okuta tẹ́.

18. Ibi ãbò fun ọjọ isimi ti a kọ́ ninu ile na, ati ọ̀na ijade si ode ti ọba, ni o yipada kuro ni ile Oluwa nitori ọba Assiria.

19. Ati iyokù iṣe Ahasi ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

20. Ahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.