Yorùbá Bibeli

Joṣ 9:15-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn.

16. O si ṣe li opin ijọ́ mẹta, lẹhin ìgbati nwọn bá wọn dá majẹmu, ni nwọn gbọ́ pe aladugbo wọn ni nwọn, ati pe làrin wọn ni nwọn gbé wà.

17. Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu.

18. Awọn ọmọ Israeli kò pa wọn, nitoriti awọn olori ijọ awọn enia ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn. Gbogbo ijọ awọn enia si kùn si awọn olori.

19. Ṣugbọn gbogbo awọn olori wi fun gbogbo ijọ pe, Awa ti fi OLUWA, Ọlọrun Israeli, bura fun wọn: njẹ nitorina awa kò le fọwọkàn wọn.

20. Eyi li awa o ṣe si wọn, ani awa o da wọn si, ki ibinu ki o má ba wà lori wa, nitori ibura ti a bura fun wọn.

21. Awọn olori si wi fun wọn pe, Ẹ da wọn si: nwọn si di aṣẹ́gi ati apọnmi fun gbogbo ijọ; gẹgẹ bi awọn olori ti sọ fun wọn.