Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 6:19-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Eliṣa si wi fun wọn pe, Eyi kì iṣe ọ̀na, bẹ̃ni eyi kì iṣe ilu na: ẹ ma tọ̀ mi lẹhin, emi o si mu nyin wá ọdọ ọkunrin ti ẹnyin nwá. O si ṣe amọ̀na wọn lọ si Samaria.

20. O si ṣe, nigbati nwọn de Samaria ni Eliṣa wipe, Oluwa la oju awọn enia wọnyi, ki nwọn ki o lè riran. Oluwa si là oju wọn; nwọn si riran; si kiyesi i, nwọn mbẹ li ãrin Samaria.

21. Ọba Israeli si wi fun Eliṣa, nigbati o ri wọn pe, Baba mi, ki emi ki o mã pa wọn bi? ki emi ki o mã pa wọn bi?

22. On si dahùn pe, Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ, ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ̀ oluwa wọn lọ.

23. On si pèse ọ̀pọlọpọ onjẹ fun wọn; nigbati nwọn si ti jẹ, ti nwọn si ti mu tan, o rán wọn lọ, nwọn si tọ̀ oluwa wọn lọ. Bẹ̃ni ẹgbẹ́ ogun Siria kò tun wá si ilẹ Israeli mọ.

24. O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria.

25. Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun.

26. O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba!

27. On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti?