Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 5:19-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. On si wi fun u pe, Mã lọ ni alãfia. Bẹ̃ni o si jade lọ jinà diẹ kuro lọdọ rẹ̀.

20. Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀.

21. Bẹ̃ni Gehasi lepa Naamani. Nigbati Naamani ri ti nsare bọ̀ lẹhin on, o sọ̀kalẹ kuro ninu kẹkẹ́ lati pade rẹ̀, o si wipe, Alafia kọ?

22. On si wipe, Alafia ni. Oluwa mi rán mi, wipe, Kiyesi i, nisisiyi ni ọdọmọkunrin meji ninu awọn ọmọ woli ti òke Efraimu wá ọdọ mi; emi bẹ̀ o, fun wọn ni talenti fadakà kan, ati ipàrọ aṣọ meji.

23. Naamani si wipe, Fi ara balẹ, gbà talenti meji. O si rọ̀ ọ, o si dì talenti fadakà meji sinu apò meji, pẹlu ipàrọ aṣọ meji, o si gbé wọn rù ọmọ-ọdọ rẹ̀ meji; nwọn si rù wọn niwaju rẹ̀.

24. Nigbati o si de ibi ile ìṣọ, o gbà wọn lọwọ wọn, o si tò wọn sinu ile: o si jọ̀wọ awọn ọkunrin na lọwọ lọ, nwọn si jade lọ.

25. Ṣugbọn on wọ̀ inu ile lọ, o si duro niwaju oluwa rẹ̀. Eliṣa si wi fun u pe, Gehasi, nibo ni iwọ ti mbọ̀? On si wipe, Iranṣẹ rẹ kò lọ ibikibi.

26. On si wi fun u pe, Ọkàn mi kò ha ba ọ lọ, nigbati ọkunrin na fi yipada kuro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ lati pade rẹ? Eyi ha iṣe akokò ati gbà fadakà, ati lati gbà aṣọ, ati ọgbà-olifi ati ọgbà-ajara, ati àgutan, ati malu, ati iranṣékunrin ati iranṣẹbinrin?