On si wipe, Alafia ni. Oluwa mi rán mi, wipe, Kiyesi i, nisisiyi ni ọdọmọkunrin meji ninu awọn ọmọ woli ti òke Efraimu wá ọdọ mi; emi bẹ̀ o, fun wọn ni talenti fadakà kan, ati ipàrọ aṣọ meji.