Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 3:6-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Jehoramu ọba si jade lọ kuro ni Samaria li akoko na, o si ka iye gbogbo Israeli.

7. O si lọ, o ranṣẹ si Jehoṣafati ọba Juda, wipe, Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ si mi: iwọ o ha bá mi lọ si Moabu lati jagun? On si wipe, Emi o gòke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.

8. On si wipe, Ọ̀na wo li awa o gbà gòke lọ? On si dahùn wipe, Ọ̀na aginju Edomu.

9. Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin.

10. Ọba Israeli si wipe, O ṣe! ti Oluwa fi pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ!

11. Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi.

12. Jehoṣafati si wipe, Ọ̀rọ Oluwa mbẹ pẹlu rẹ̀. Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati ati ọba Edomu sọ̀kalẹ tọ̀ ọ lọ.

13. Eliṣa si wi fun ọba Israeli pe, Kini o ṣe mi ṣe ọ? Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃kọ: nitori ti Oluwa ti pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ.

14. Eliṣa si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, iba má ṣepe mo bu ọwọ Jehoṣafati ọba Juda, nitõtọ emi kì ba ti bẹ̀ ọ wò, bẹ̃ni emi kì ba ti ri ọ.

15. Ṣugbọn ẹ mu akọrin kan fun mi wá nisisiyi. O si ṣe, nigbati akọrin na nkọrin, ọwọ Oluwa si bà le e.

16. On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wà iho pupọ li afonifojì yi.

17. Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin.

18. Ohun kikini si li eyi loju Oluwa: on o fi awọn ara Moabu le nyin lọwọ pẹlu.

19. Ẹnyin o si kọlù gbogbo ilu olodi, ati gbogbo ãyò ilu, ẹnyin o si ké gbogbo igi rere lulẹ, ẹnyin o si dí gbogbo kanga omi, ẹnyin o si fi okuta bà gbogbo oko rere jẹ.