Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 19:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀; Wundia ọmọbinrin Sioni ti kẹgàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ.

22. Tani iwọ sọ̀rọ buburu si ti iwọ si kẹgàn? ati tani iwọ gbé ohùn rẹ si òke si, ti iwọ gbé oju rẹ ga si òke? ani si Ẹni-Mimọ Israeli.

23. Nipa awọn onṣẹ rẹ, iwọ ti sọ̀rọ buburu si Oluwa, ti nwọn si wipe, Ọpọlọpọ kẹkẹ́ mi li emi fi de ori awọn òke-nla, si ori Lebanoni, emi o si ké igi kedari giga rẹ̀ lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀; emi o si lọ si ori òke ibùwọ rẹ̀, sinu igbó Karmeli rẹ̀.

24. Emi ti wà kànga, emi si ti mu ajèji omi, atẹlẹsẹ̀ mi li emi si ti fi gbẹ gbogbo odò Egipti.

25. Iwọ kò ti gbọ́, lailai ri emi ti ṣe e, nigba atijọ emi si ti mura tẹlẹ nisisiyi emi ti mu u ṣẹ, ki iwọ ki o le mã sọ ilu olodi wọnni di ahoro, ani di òkiti àlapa.

26. Nitorina ni awọn olugbe wọn fi ṣe alainipa, a daiyàfo wọn nwọn si dãmu; nwọn dàbi koriko igbẹ́, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko li ori ile, ati bi ọkà ti o rẹ̀ danù ki o to dàgba soke.

27. Ṣugbọn emi mọ̀ ijoko rẹ, ati ijadelọ rẹ, ati bibọ̀ rẹ, ati ikannu rẹ si mi.

28. Nitori ikánnu rẹ si mi ati irera rẹ de eti mi, nitorina li emi o fi ìwọ̀ mi kọ́ ọ ni imu, ati ijanu mi si ẹnu rẹ, emi o si yi ọ pada si ọ̀na na ti iwọ ti ba wá.

29. Eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun ni, ati li ọdun keji eyiti o hù ninu ọkanna; ati li ọdun kẹta ẹ fun irúgbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba ajara, ki ẹ si jẹ eso rẹ̀.