Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 18:5-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. O gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun Israeli; ati lẹhin rẹ̀ kò si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọba Juda, bẹ̃ni ṣãju rẹ̀ kò si ẹnikan.

6. Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose.

7. Oluwa si wà pẹlu rẹ̀; o si ṣe rere nibikibi ti o ba jade lọ: o si ṣọ̀tẹ si ọba Assiria, kò si sìn i mọ.

8. On kọlù awọn ara Filistia, ani titi de Gasa, ati agbègbe rẹ̀, lati ile iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.

9. O si ṣe li ọdun kẹrin Hesekiah ọba, ti iṣe ọdun keje Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli, ni Ṣalmaneseri ọba Assiria gòke wá si Samaria, o si dotì i.

10. Lẹhin ọdun mẹta nwọn kó o; ani li ọdun kẹfa Hesekiah, eyini ni ọdun kẹsan Hoṣea ọba Israeli li a kó Samaria.

11. Ọba Assiria si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori leti odò Gosani, ati si ilẹ awọn ara Media wọnni:

12. Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.

13. Li ọdun kẹrinla Hesekiah ọba, ni Sennakeribu ọba Assiria gòke wá si gbogbo awọn ilu olodi Juda, o si kó wọn.

14. Hesekiah ọba Juda si ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wipe, Mo ti ṣẹ̀; padà lẹhin mi: eyiti iwọ ba bù fun mi li emi o rù. Ọba Assiria si bù ọ̃dunrun talenti fadakà, ati ọgbọ̀n talenti wura fun Hesekiah ọba Juda.

15. Hesekiah si fun u ni gbogbo fadakà ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba.

16. Li akòko na ni Hesekiah ké gbogbo wura kuro lara awọn ilẹ̀kun ile Oluwa, ati kuro lara ọwọ̀n wọnni ti Hesekiah ọba Juda ti fi wura bò, o si fi wọn fun ọba Assiria.

17. Ọba Assiria si rán Tartani, ati Rabsarisi, ati Rabṣake, lati Lakiṣi lọ si ọdọ Hesekiah ọba pẹlu ogun nla si Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn si de Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn de, nwọn si duro leti idari omi abàta òke, ti mbẹ li eti òpopo pápa afọṣọ.

18. Nigbati nwọn si ké si ọba, Eliakimu ọmọ Hilkiah ti iṣe olori ile na si jade tọ̀ wọn wá, ati Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu akọwe-iranti.

19. Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ sọ fun Hesekiah nisisiyi pe, Bayi ni ọba nla, ọba Assiria wi pe, Kini igbẹkẹle yi ti iwọ gbẹkẹle?

20. Iwọ wipe (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn), emi ni ìmọ ati agbara lati jagun. Njẹ tani iwọ gbẹkẹle, ti iwọ fi ṣọ̀tẹ si mi?

21. Kiyesi i, nisisiyi, iwọ gbẹkẹle ọ̀pa iyè fifọ yi, ani le Egipti, lara ẹniti bi ẹnikan ba fi ara tì, yio wọ̀ ọ li ọwọ lọ, yio si gun u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.