Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 13:16-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. O si wi fun ọba Israeli pe, Fi ọwọ rẹ le ọrun na: on si fi ọwọ rẹ̀ le e: Eliṣa si fi ọwọ tirẹ̀ le ọwọ ọba.

17. O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn.

18. O si wipe, Kó awọn ọfà na. O si kó wọn. O si wi fun ọba Israeli pe, Ta si ilẹ. On si ta lẹrinmẹta, o si mu ọwọ duro.

19. Enia Ọlọrun na si binu si i, o si wipe, Iwọ iba ta lẹrinmarun tabi mẹfa; nigbana ni iwọ iba kọlù Siria titi iwọ iba fi run u: ṣugbọn nisisiyi iwọ o kọlù Siria nigbà mẹta.

20. Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun.

21. O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.

22. Ṣugbọn Hasaeli ọba Siria ni Israeli lara ni gbogbo ọjọ Jehoahasi.

23. Oluwa si ṣe oju rere si wọn, o si ṣãnu fun wọn, o si ṣe akiyesi wọn, nitoriti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, kò si fẹ run wọn, bẹ̃ni kò si ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀ titi di isisiyi.

24. Bẹ̃ni Hasaeli ọba Siria kú; Benhadadi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

25. Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi si tun gbà ilu wọnni pada lọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, ti o ti fi ogun gbà lọwọ Jehoahasi baba rẹ̀. Igba mẹta ni Joaṣi ṣẹgun rẹ̀, o si gbà awọn ilu Israeli pada.