Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 10:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si ṣe, nigbati iwe na de ọdọ wọn, ni nwọn mu awọn ọmọ ọba, nwọn si pa ãdọrin ọkunrin, nwọn si kó ori wọn sinu agbọ̀n, nwọn si fi wọn ranṣẹ si i ni Jesreeli.

8. Onṣẹ kan si de, o si sọ fun u, wipe, nwọn ti mu ori awọn ọmọ ọba wá. On si wipe, Ẹ tò wọn li okiti meji ni atiwọ̀ ẹnu bodè, titi di owurọ̀.

9. O si ṣe li owurọ̀, o si jade lọ, o si duro, o si wi fun gbogbo awọn enia pe, Olododo li ẹnyin: kiyesi i, emi ṣọ̀tẹ si oluwa mi, mo si pa a: ṣugbọn tani pa gbogbo awọn wọnyi?

10. Njẹ ẹ mọ̀ pe, kò si ohunkan ninu ọ̀rọ Oluwa, ti Oluwa sọ niti ile Ahabu ti yio bọ́ silẹ, nitori ti Oluwa ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀.

11. Bẹ̃ni Jehu pa gbogbo awọn ti o kù ni ile Ahabu ni Jesreeli ati gbogbo awọn enia nla rẹ̀, ati awọn ibatan rẹ̀, ati awọn alufa rẹ̀, titi on kò fi kù ọkan silẹ fun u.

12. On si dide, o si mbọ̀ o si wá si Samaria: bi o si ti wà nibi ile irẹ́run agutan li oju ọ̀na.

13. Jehu pade awọn arakunrin Ahasiah ọba Juda, o si wipe, Tali ẹnyin? Nwọn si dahùn wipe, Awa arakunrin Ahasiah ni; awa si nsọ̀kalẹ lati lọ ikí awọn ọmọ ọba ati awọn ọmọ ayaba.

14. On si wipe, Ẹ mu wọn lãyè, nwọn si mu wọn lãyè, nwọn si pa wọn nibi iho ile irẹ́run agùtan, ani ọkunrin mejilelogoji, bẹ̃ni kò si kù ẹnikan wọn.

15. Nigbati o si jade nibẹ, o ri Jehonadabu ọmọ Rekabu mbọ̀wá ipade rẹ̀; o si sure fun u, o si wi fun u pe, Ọkàn rẹ ha ṣe dede bi ọkàn mi ti ri si ọkàn rẹ? Jehonadabu si dahùn wipe, Bẹ̃ni. Bi bẹ̃ni, njẹ fun mi li ọwọ rẹ. O si fun u li ọwọ rẹ̀; on si fà a sọdọ rẹ̀ sinu kẹkẹ́.

16. On si wipe, Ba mi lọ ki o si wò itara mi fun Oluwa. Bẹ̃ni nwọn mu u gùn kẹkẹ́ rẹ̀.