Yorùbá Bibeli

2. Sam 2:17-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ijà na si kan gidigidi ni ijọ na, a si le Abneri ati awọn ọkunrin Israeli niwaju awọn ọmọ Dafidi.

18. Awọn ọmọ Seruia mẹtẹta si mbẹ nibẹ, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fẹrẹ bi ẹsẹ agbọnrin ti o wà ni pápa.

19. Asaheli si nlepa Abneri; bi on ti nlọ kò si yipada si ọwọ ọtun, tabi si ọwọ́ osì lati ma tọ Abneri lẹhin.

20. Nigbana ni Abneri boju wo ẹhin rẹ̀, o si bere pe, Iwọ Asaheli ni? On si dahùn pe, Emi ni.

21. Abneri si wi fun u pe, Iwọ yipada si apakan si ọwọ́ ọtun rẹ, tabi si osì rẹ, ki iwọ ki o si di ọkan mu ninu awọn ọmọkunrin, ki o si mu ihamọra rẹ̀. Ṣugbọn Asaheli kọ̀ lati pada lẹhin rẹ̀.

22. Abneri si tun wi fun Asaheli pe, Pada lẹhin mi, ẽṣe ti emi o fi lu ọ bolẹ? bawo li emi o ti ṣe gbe oju soke si Joabu arakunrin rẹ?

23. Ṣugbọn o si kọ̀ lati pada: Abneri si fi òdi ọ̀kọ gun u labẹ inu, ọ̀kọ na si jade li ẹhin rẹ̀: on si ṣubu lulẹ nibẹ, o si kú ni ibi kanna; o si ṣe, gbogbo enia ti o de ibiti Asaheli gbe ṣubu si, ti o si kú, si duro jẹ.

24. Joabu ati Abiṣai si lepa Abneri: õrun si wọ̀, nwọn si de oke ti Amma ti o wà niwaju Gia li ọ̀na iju Gibeoni.

25. Awọn ọmọ Benjamini si ko ara wọn jọ nwọn tẹle Abneri, nwọn si wa di ẹgbẹ kan, nwọn si duro lori oke kan.

26. Abneri si pe Joabu, o si bi i lere pe, Idà yio ma parun titi lailai bi? njẹ iwọ kò iti mọ̀ pe yio koro nikẹhin? njẹ yio ha ti pẹ to ki iwọ ki o to sọ fun awọn enia na, ki nwọn ki o dẹkun lati ma lepa ará wọn?

27. Joabu si wipe, Bi Ọlọrun ti mbẹ, bikoṣe bi iwọ ti wi, nitotọ, li owurọ̀ li awọn enia na iba ti goke lọ, olukuluku iba ti pada lẹhin arakunrin rẹ̀.

28. Joabu si fún ipè, gbogbo enia si duro jẹ, nwọn kò si lepa Israeli mọ, bẹ̃ni nwọn kò si tun jà mọ.

29. Abneri ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si fi gbogbo oru na rìn ni pẹtẹlẹ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si rìn ni gbogbo Bitroni, nwọn si wá si Mahanaimu.

30. Joabu si dẹkun ati ma tọ Abneri lẹhin: o si ko gbogbo awọn enia na jọ, enia mọkandi-logun li o kú pẹlu Asaheli ninu awọn iranṣẹ Dafidi.

31. Ṣugbọn awọn iranṣẹ Dafidi si lù bolẹ ninu awọn enia Benjamini; ati ninu awọn ọmọkunrin Abneri; ojì-di-ni-irin-wo enia li o kú.

32. Nwọn si gbe Asaheli, nwọn si sin i sinu ibojì baba rẹ̀ ti o wà ni Betlehemu. Joabu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ fi gbogbo oru na rin, ilẹ si mọ́ wọn si Hebroni.