Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 4:32-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Nigbati Eliṣa si wọ̀ inu ile, kiyesi i, ọmọ na ti kú, a si tẹ́ ẹ sori ibùsun rẹ̀.

33. O si wọ̀ inu ile lọ, o si se ilẹ̀kun mọ awọn mejeji, o si gbadura si Oluwa.

34. On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná.

35. O si pada, o si rìn lọ, rìn bọ̀ ninu ile lẹ̃kan; o si gòke, o si nà ara rẹ̀ le e; ọmọ na si sín nigba meje; ọmọ na si là oju rẹ̀.

36. O si pè Gehasi, o si wipe, Pè ara Ṣunemu yi wá. O si pè e. Nigbati o si wọle tọ̀ ọ wá, o ni, Gbé ọmọ rẹ.

37. Nigbana li o wọ̀ inu ile, o si wolẹ li ẹba ẹṣẹ̀ rẹ̀, o si dojubolẹ, o si gbé ọmọ rẹ̀, o si jade lọ.

38. Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli.

39. Ẹnikan si jade lọ si igbẹ lati fẹ́ ewebẹ̀, o si ri ajara-igbẹ kan, o si ka eso rẹ̀ kún aṣọ rẹ̀, o si rẹ́ ẹ wẹwẹ, o dà wọn sinu ikoko ipẹ̀tẹ na: nitoripe nwọn kò mọ̀ wọn.

40. Bẹ̃ni nwọn si dà a fun awọn ọkunrin na lati jẹ. O si ṣe bi nwọn ti njẹ ipẹ̀tẹ na, nwọn si kigbe, nwọn si wipe, Iwọ enia Ọlọrun, ikú mbẹ ninu ikoko na! Nwọn kò si le jẹ ẹ.

41. Ṣugbọn on wipe, Njẹ, ẹ mu iyẹ̀fun wá. O si dà a sinu ikoko na, o si wipe, Dà a fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. Kò si si jamba ninu ikoko mọ.