Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 4:22-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. On si ke si ọkọ rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, rán ọkan ninu awọn ọdọmọkunrin si mi, ati ọkan ninu awọn kẹtẹkẹtẹ, emi o si sare tọ̀ enia Ọlọrun lọ, emi o si tun pada.

23. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ o fi tọ̀ ọ lọ loni? kì isa ṣe oṣù titun, bẹ̃ni kì iṣe ọjọ isimi. On sì wipe, Alafia ni.

24. Nigbana li o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, o si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Mã le e, ki o si ma nṣo; máṣe dẹ̀ ire fun mi, bikòṣepe mo sọ fun ọ.

25. Bẹ̃li o lọ, o si de ọdọ enia Ọlọrun na li òke Karmeli. O si ṣe, nigbati enia Ọlọrun na ri i li okère, o si sọ fun Gehasi ọmọ ọdọ rẹ̀ pe, Wò ara Ṣunemu nì:

26. Emi bẹ̀ ọ, sure nisisiyi ki o pade rẹ̀, ki o si wi fun u pe, Alafia ki o wà bi? alafia ki ọkọ rẹ̀ wà bi? alafia ki ọmọde wà bi? On si dahùn wipe, Alafia ni.

27. Nigbati o si de ọdọ enia Ọlọrun li ori òke, o gbá a li ẹsẹ̀ mu: ṣugbọn Gehasi sunmọ ọ lati tì i kurò. Enia Ọlọrun na si wipe, Jọwọ rẹ̀ nitori ọkàn rẹ̀ bajẹ ninu rẹ̀, Oluwa si pa a mọ́ fun mi, kò si sọ fun mi.

28. Nigbana li o wipe, Mo ha tọrọ ọmọ li ọwọ oluwa mi bi? Emi kò ha wipe, Máṣe tàn mi jẹ?

29. O si wi fun Gehasi pe, Di àmure rẹ, ki o si mu ọpa mi li ọwọ rẹ, ki o si lọ, bi iwọ ba ri ẹnikẹni li ọ̀na, máṣe ki i; bi ẹnikeni ba si kí ọ, máṣe da a li ohùn: ki o si fi ọpá mi le iwaju ọmọ na.

30. Iya ọmọ na si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. On si dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin.

31. Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji.