Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 3:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Eliṣa si wi fun ọba Israeli pe, Kini o ṣe mi ṣe ọ? Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃kọ: nitori ti Oluwa ti pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ.

14. Eliṣa si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, iba má ṣepe mo bu ọwọ Jehoṣafati ọba Juda, nitõtọ emi kì ba ti bẹ̀ ọ wò, bẹ̃ni emi kì ba ti ri ọ.

15. Ṣugbọn ẹ mu akọrin kan fun mi wá nisisiyi. O si ṣe, nigbati akọrin na nkọrin, ọwọ Oluwa si bà le e.

16. On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Wà iho pupọ li afonifojì yi.

17. Nitori bayi li Oluwa wi, pe, Ẹnyin kì o ri afẹfẹ, bẹ̃ni ẹnyin kì o ri òjo; ṣugbọn afonifojì na yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọ̀sin nyin, ati ẹran nyin.

18. Ohun kikini si li eyi loju Oluwa: on o fi awọn ara Moabu le nyin lọwọ pẹlu.

19. Ẹnyin o si kọlù gbogbo ilu olodi, ati gbogbo ãyò ilu, ẹnyin o si ké gbogbo igi rere lulẹ, ẹnyin o si dí gbogbo kanga omi, ẹnyin o si fi okuta bà gbogbo oko rere jẹ.

20. O si ṣe li owurọ, bi a ti nta ọrẹ-ẹbọ onjẹ, si kiyesi i, omi ti ọ̀na Edomu wá, ilẹ na si kún fun omi.