Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 25:19-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ati lati inu ilu, o mu iwẹ̀fa kan ti a fi ṣe olori awọn ologun, ati ọkunrin marun ninu awọn ti o wà niwaju ọba, ti a ri ni ilu, ati akọwe olori ogun, ti ntò awọn enia ilẹ na, ati ọgọta ọkunrin ninu awọn enia ilẹ na ti a ri ni ilu.

20. Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ si kó awọn wọnyi, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.

21. Ọba Babeli si kọlù wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.

22. Ati awọn enia ti o kù ni ilẹ Juda, ti Nebukadnessari ọba Babeli fi silẹ, ani, o fi Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, jẹ bãlẹ wọn.

23. Nigbati gbogbo awọn olori ogun, awọn ati awọn ọkunrin wọn, si gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah jẹ bãlẹ, nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ati Johanani ọmọ Karea, ati Seraiah ọmọ Tanhumeti ara Netofati, ati Jaasaniah ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn.

24. Gedaliah si bura fun wọn, ati fun awọn ọkunrin wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru lati sìn awọn ara Kaldea: ẹ mã gbe ilẹ na, ki ẹ si mã sìn ọba Babeli; yio si dara fun nyin.

25. O si ṣe li oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama ninu iru ọmọ ọba, wá ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, o si kọlù Gedaliah, o si kú, ati awọn ara Juda ati awọn ara Kaldea ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Mispa.

26. Ati gbogbo enia, ti ewe ti àgba, ati awọn olori ogun, si dide, nwọn si wá si Egipti: nitoriti nwọn bẹ̀ru ara Kaldea.

27. O si ṣe li ọdun kẹtadilogoji igbèkun Jehoiakini ọba Juda, li oṣù kejila, li ọjọ kẹtadilọgbọn oṣù, Efil-merodaki ọba Babeli, li ọdun ti o bẹ̀rẹ si ijọba, o gbé ori Jehoiakini ọba Juda soke kuro ninu tubu;

28. O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbé ìtẹ rẹ̀ ga jù ìtẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli.

29. O si pàrọ awọn aṣọ tubu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

30. Ati ipin onjẹ tirẹ̀, jẹ ipin onjẹ ti ọba nfi fun u nigbagbogbo, iye kan li ojojumọ, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.