Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 25:12-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ṣugbọn olori ẹ̀ṣọ fi awọn talakà ilẹ na silẹ, lati mã ṣe alabojuto àjara ati lati mã ṣe aroko.

13. Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ ni ile Oluwa, ati ijoko wọnni, ati agbada-nla idẹ ti o wà ni ile Oluwa, li awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó idẹ wọn lọ si Babeli.

14. Ati ikòko wọnni, ati ọkọ wọnni, ati alumagàji fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun-èlo wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ, ni nwọn kó lọ.

15. Ati ohun ifọnná wọnni, ati ọpọ́n wọnni, eyi ti iṣe ti wura, ni wura, ati eyi ti iṣe ti fadakà ni fadakà, ni olori ẹ̀ṣọ kó lọ.

16. Awọn ọ̀wọn meji, agbada-nla kan, ati ijoko wọnni ti Solomoni ti ṣe fun ile Oluwa; idẹ ni gbogbo ohun-èlo wọnyi, alaini ìwọn ni.

17. Giga ọwọ̀n kan ni igbọ̀nwọ mejidilogun, ati ọnà-ori rẹ̀ idẹ ni: ati giga ọnà-ori na ni igbọ̀nwọ mẹta; ati iṣẹ wiwun na, ati awọn pomegranate ti o wà lori ọnà-ori na yika kiri, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹgẹ bi awọn wọnyi si ni ọwọ̀n keji pẹlu iṣẹ wiwun.

18. Olori ẹ̀ṣọ si mu Seraiah olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah alufa keji, ati awọn olùṣọ iloro mẹta.

19. Ati lati inu ilu, o mu iwẹ̀fa kan ti a fi ṣe olori awọn ologun, ati ọkunrin marun ninu awọn ti o wà niwaju ọba, ti a ri ni ilu, ati akọwe olori ogun, ti ntò awọn enia ilẹ na, ati ọgọta ọkunrin ninu awọn enia ilẹ na ti a ri ni ilu.

20. Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ si kó awọn wọnyi, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.

21. Ọba Babeli si kọlù wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.

22. Ati awọn enia ti o kù ni ilẹ Juda, ti Nebukadnessari ọba Babeli fi silẹ, ani, o fi Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, jẹ bãlẹ wọn.

23. Nigbati gbogbo awọn olori ogun, awọn ati awọn ọkunrin wọn, si gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah jẹ bãlẹ, nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ati Johanani ọmọ Karea, ati Seraiah ọmọ Tanhumeti ara Netofati, ati Jaasaniah ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn.