Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 23:24-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ati pẹlu awọn ti mba awọn okú lò, ati awọn oṣo, ati awọn ere, ati awọn oriṣa, ati gbogbo irira ti a ri ni ilẹ Juda ati ni Jerusalemu ni Josiah kó kuro, ki o le mu ọ̀rọ ofin na ṣẹ ti a ti kọ sinu iwe ti Hilkiah alufa ri ni ile Oluwa.

25. Kò si si ọba kan ṣãju rẹ̀, ti o dabi rẹ̀, ti o yipada si Oluwa tinutinu ati tọkàntọkàn ati pẹlu gbogbo agbara rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo ofin Mose; bẹ̃ni lẹhin rẹ̀, kò si ẹnikan ti o dide ti o dàbi rẹ̀.

26. Ṣugbọn Oluwa kò yipada kuro ninu mimuná ibinu nla rẹ̀, eyiti ibinu rẹ̀ fi ràn si Juda, nitori gbogbo imunibinu ti Manasse ti fi mu u binu.

27. Oluwa si wipe, Emi o si mu Juda kuro loju mi pẹlu, bi mo ti mu Israeli kuro, emi o si ta ilu Jerusalemu yi nù, ti mo ti yàn, ati ile eyiti mo wipe, Orukọ mi yio wà nibẹ.

28. Ati iyokù iṣe Josiah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

29. Li ọjọ rẹ̀ ni Farao-Neko ọba Egipti dide ogun si ọba Assiria li odò Euferate: Josiah ọba si dide si i; on si pa a ni Megiddo, nigbati o ri i.

30. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e li okú ninu kẹkẹ́ lati Megiddo lọ, nwọn si mu u wá si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni isà-okú on tikalarẹ̀. Awọn enia ilẹ na si mu Jehoahasi ọmọ Josiah, nwọn si fi ororo yàn a, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀.

31. Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna,

32. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.

33. Farao-Neko si fi i sinu idè ni Ribla, ni ilẹ Hamati, ki o má ba jọba ni Jerusalemu; o si fi ilẹ na si abẹ isìn li ọgọrun talenti fadakà, ati talenti wura.

34. Farao-Neko si fi Eliakimu ọmọ Josiah jẹ ọba ni ipò Josiah baba rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu, o si mu Jehoahasi kuro; on si wá si Egipti, o si kú nibẹ.

35. Jehoiakimu si fi fadakà ati wura na fun Farao; ṣugbọn o bu owo-odè fun ilẹ na lati san owo na gẹgẹ bi ofin Farao: o fi agbara gbà fadakà ati wurà na lọwọ awọn enia ilẹ na, lọwọ olukuluku gẹgẹ bi owo ti a bù fun u, lati fi fun Farao-Neko.

36. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jehoiakimu nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Sebuda, ọmọbinrin Bedaiah ti Ruma.