Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 23:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ati ibi giga wọnni ti o wà niwaju Jerusalemu, ti o wà li ọwọ ọtún òke idibàjẹ, ti Solomoni ọba Israeli ti kọ́ fun Aṣtoreti ohun irira awọn ara Sidoni, ati fun Kemoṣi ohun irira awọn ara Moabu, ati fun Milkomu ohun-irira awọn ọmọ Ammoni li ọba sọ di ẽri.

14. O si fọ́ awọn ere na tũtu, o si wó awọn ere-oriṣa lulẹ, o si fi egungun enia kún ipò wọn.

15. Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na.

16. Bi Josiah si ti yira pada, o ri awọn isà-okú ti o wà lori òke, o si ranṣẹ, o si kó awọn egungun lati inu isà wọnni kuro, o si sun wọn lori pẹpẹ na, o si sọ ọ di ẽri, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti enia Ọlọrun nì ti kede, ẹniti o kede ọ̀ro wọnyi.

17. Nigbana li o wipe, Ọwọ̀n isa-okú wo li eyi ti mo ri nì? Awọn enia ilu na si sọ fun u pe, Isà-okú enia Ọlọrun nì ni, ti o ti Juda wá, ti o si kede nkan wọnyi ti iwọ ti ṣe si pẹpẹ Beteli.

18. On si wipe, Jọwọ rẹ̀; máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mu egungun rẹ̀ kuro. Bẹ̃ni nwọn jọwọ egungun rẹ̀ lọwọ, pẹlu egungun woli ti o ti Samaria wá.

19. Ati pẹlu gbogbo ile ibi-giga wọnni ti o wà ni ilu Samaria wọnni, ti awọn ọba Israeli ti kọ́ lati rú ibinu Oluwa soke ni Josiah mu kuro, o si ṣe si wọn gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti o ṣe ni Beteli.

20. O si pa gbogbo awọn alufa ibi-giga wọnni ti o wà nibẹ lori awọn pẹpẹ na, o si sun egungun enia lori wọn, o si pada si Jerusalemu.