Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 23:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌBA si ranṣẹ, nwọn si pè gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ sọdọ rẹ̀.

2. Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo awọn enia Juda ati gbogbo olugbe Jerusalemu pẹlu rẹ̀, ati awọn alufa, ati awọn woli ati gbogbo enia, ati ewe ati àgba: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.

3. Ọba si duro ni ibuduro na, o si dá majẹmu niwaju Oluwa, lati mã fi gbogbo aìya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati mu ọ̀rọ majẹmu yi ṣẹ, ti a ti kọ ninu iwe yi. Gbogbo awọn enia si duro si majẹmu na.

4. Ọba si paṣẹ fun Hilkiah olori alufa, ati awọn alufa ẹgbẹ keji, ati awọn alabojuto iloro, lati kó gbogbo ohun-èlo ti a ṣe fun Baali, ati fun ere òriṣa, ati fun gbogbo ogun ọrun jade kuro ni tempili Oluwa: o si sun wọn lẹhin ode Jerusalemu ninu pápa Kidroni, o si kó ẽru wọn lọ si Beteli.

5. O si dá awọn baba-loriṣa lẹkun, ti awọn ọba Juda ti yàn lati ma sun turari ni ibi giga ni ilu Juda wọnni, ati ni ibi ti o yi Jerusalemu ka; awọn pẹlu ti nsun turari fun Baali, fun õrùn, ati fun òṣupa, ati fun awọn àmi mejila ìrawọ, ati fun gbogbo ogun ọrun.

6. O si gbé ere-oriṣa jade kuro ni ile Oluwa, sẹhin ode Jerusalemu lọ si odò Kidroni, o si sun u nibi odò Kidroni, o si lọ̀ ọ lũlu, o si dà ẽrú rẹ̀ sori isà-okú awọn ọmọ enia na.

7. O si wó ile awọn ti nhù ìwa panṣaga, ti mbẹ leti ile Oluwa, nibiti awọn obinrin wun aṣọ-agọ fun ere-oriṣa.

8. O si kó gbogbo awọn alufa jade kuro ni ilu Juda wọnni, o si sọ ibi giga wọnni di ẽri nibiti awọn alufa ti sun turari, lati Geba titi de Beer-ṣeba, o si wó ibi giga ẹnu-ibodè wọnni ti mbẹ ni atiwọ̀ ẹnu-ibodè Joṣua bãlẹ ilu, ti mbẹ lapa osi ẹni, ni atiwọ̀ ẹnu-ibode ilu.

9. Ṣugbọn awọn alufa ibi giga wọnni kò gòke wá si ibi pẹpẹ Oluwa ni Jerusalemu, ṣugbọn nwọn jẹ ninu àkara alaiwu lãrin awọn arakunrin wọn.

10. On si sọ Tofeti di ẽri, ti mbẹ ni afonifojì awọn ọmọ Hinnomu, ki ẹnikan ki o máṣe mu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là ãrin iná kọja fun Moleki.

11. O si mu ẹṣin wọnni kuro ti awọn ọba Juda ti fi fun õrun, ni atiwọ̀ inu ile Oluwa lẹba iyẹ̀wu Natan-meleki iwẹ̀fa, ti o ti wà ni agbegbe tempili, o si fi iná sun kẹkẹ́ õrun wọnni.

12. Ati pẹpẹ wọnni ti mbẹ lori iyara òke Ahasi, ti awọn ọba Juda ti tẹ́, ati pẹpẹ wọnni ti Manasse ti tẹ́ li ãfin mejeji ile Oluwa ni ọba wó lulẹ, o si yara lati ibẹ, o si da ekuru wọn sinu odò Kidroni.

13. Ati ibi giga wọnni ti o wà niwaju Jerusalemu, ti o wà li ọwọ ọtún òke idibàjẹ, ti Solomoni ọba Israeli ti kọ́ fun Aṣtoreti ohun irira awọn ara Sidoni, ati fun Kemoṣi ohun irira awọn ara Moabu, ati fun Milkomu ohun-irira awọn ọmọ Ammoni li ọba sọ di ẽri.

14. O si fọ́ awọn ere na tũtu, o si wó awọn ere-oriṣa lulẹ, o si fi egungun enia kún ipò wọn.

15. Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na.