Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 19:8-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bẹ̃ni Rabṣake pada, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitoriti o ti gbọ́ pe o ti lọ kuro ni Lakiṣi.

9. Nigbati o si gburo Tirhaka ọba Etiopia, pe, Kiyesi i, o jade wá lati ba ọ jagun; o si tun rán awọn onṣẹ si ọdọ Hesekiah wipe,

10. Bayi li ẹnyin o sọ fun Hesekiah ọba Juda, wipe, Máṣe jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọwọ ọba Assiria.

11. Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si gbogbo ilẹ, ni pipa wọn run patapata: a o ha si gbà iwọ bi?

12. Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun; bi Gosani, ati Harani, ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti o wà ni Telassari?

13. Nibo li ọba Hamati, ati ọba Arpadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wà?

14. Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn onṣẹ na, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ sinu ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.

15. Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye.

16. Dẹti rẹ silẹ Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: ki o si gbọ́ ọ̀rọ Sennakeribu ti o rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè.

17. Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti pa awọn orilẹ-ède run ati ilẹ wọn.

18. Nwọn si ti gbe òriṣa wọn sọ sinu iná; nitoriti nwọn kì iṣe ọlọrun, bikòṣe iṣẹ ọwọ enia, igi ati okuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run.

19. Njẹ nitorina, Oluwa Ọlọrun wa, emi mbẹ̀ ọ, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ilẹ ọba aiye le mọ̀ pe iwọ Oluwa iwọ nikanṣoṣo ni Ọlọrun.

20. Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, adura ti iwọ ti gbà si mi si Sennakeribu ọba Assiria emi ti gbọ́.