Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 18:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kẹta Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli ni Hesekiah ọmọ Ahasi ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

2. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Abi ọmọbinrin Sakariah.

3. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

4. On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani.

5. O gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun Israeli; ati lẹhin rẹ̀ kò si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọba Juda, bẹ̃ni ṣãju rẹ̀ kò si ẹnikan.

6. Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose.

7. Oluwa si wà pẹlu rẹ̀; o si ṣe rere nibikibi ti o ba jade lọ: o si ṣọ̀tẹ si ọba Assiria, kò si sìn i mọ.

8. On kọlù awọn ara Filistia, ani titi de Gasa, ati agbègbe rẹ̀, lati ile iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.

9. O si ṣe li ọdun kẹrin Hesekiah ọba, ti iṣe ọdun keje Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli, ni Ṣalmaneseri ọba Assiria gòke wá si Samaria, o si dotì i.

10. Lẹhin ọdun mẹta nwọn kó o; ani li ọdun kẹfa Hesekiah, eyini ni ọdun kẹsan Hoṣea ọba Israeli li a kó Samaria.

11. Ọba Assiria si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori leti odò Gosani, ati si ilẹ awọn ara Media wọnni:

12. Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.