Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 16:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kẹtadilogun Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

2. Ẹni ogún ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu, kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

3. Ṣugbọn o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, nitõtọ, o si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná pẹlu, gẹgẹ bi iṣe irira awọn keferi, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.

4. O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori awọn òke kekeke, ati labẹ gbogbo igi tutu.

5. Nigbana ni Resini ọba Siria ati Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli gòke wá si Jerusalemu lati jagun: nwọn si do tì Ahasi, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.

6. Li akokò na, Resini ọba Siria gbà Elati pada fun Siria, o si lé awọn enia Juda kuro ni Elati: awọn ara Siria si wá si Elati, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.

7. Ahasi si rán onṣẹ si ọdọ Tiglat-pileseri ọba Assiria wipe, Iranṣẹ rẹ li emi, ati ọmọ rẹ; gòke wá, ki o si gbà mi lọwọ ọba Siria, ati lọwọ ọba Israeli, ti o dide si mi.

8. Ahasi si mu fadakà ati wura ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, o si rán a li ọrẹ si ọba Assiria.