Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 13:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kẹtalelogun Joaṣi ọmọ Ahasiah ọba Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria.

2. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, o si tẹ̀le ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: on kò si lọ kuro ninu rẹ̀.

3. Ibinu Oluwa si rú si Israeli, o si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, li ọjọ wọn gbogbo.

4. Jehoahasi si bẹ̀ Oluwa, Oluwa si gbọ́ tirẹ̀; nitoriti o ri inira Israeli, nitoriti ọba Siria ni wọn lara.

5. Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ.

6. Ṣugbọn nwọn kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ṣugbọn nwọn rìn ninu rẹ̀: ere-oriṣa si wà ni Samaria pẹlu.

7. Bẹ̃ni kò kù ninu awọn enia fun Jehoahasi, bikòṣe ãdọta ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́ mẹwa, ati ẹgbãrin ẹlẹsẹ̀; nitoriti ọba Siria ti pa wọn run, o si ti lọ̀ wọn mọlẹ bi ẽkuru.

8. Ati iyokù iṣe Jehoahasi, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

9. Jehoahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i ni Samaria: Joaṣi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.