Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 20:20-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Nwọn si pa, olukuluku ọkunrin kọkan; awọn ara Siria sa; Israeli si lepa wọn: Benhadadi, ọba Siria si sala lori ẹṣin pẹlu awọn ẹlẹṣin.

21. Ọba Israeli si jade lọ, o si kọlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ́, o pa awọn ara Siria li ọ̀pọlọpọ.

22. Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.

23. Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ.

24. Nkan yi ni ki o si ṣe, mu awọn ọba kuro, olukuluku kuro ni ipò rẹ̀, ki o si fi olori-ogun si ipò wọn.

25. Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃.

26. O si ṣe li amọdun, ni Benhadadi kà iye awọn ara Siria, nwọn si goke lọ si Afeki, lati bá Israeli jagun.

27. A si ka iye awọn ọmọ Israeli, nwọn si pese onjẹ, nwọn si lọ ipade wọn: awọn ọmọ Israeli si dó niwaju wọn gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji: ṣugbọn awọn ara Siria kún ilẹ na.

28. Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.

29. Nwọn si dó, ekini tì ekeji ni ijọ meje. O si ṣe, li ọjọ keje, nwọn padegun, awọn ọmọ Israeli si pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ̀ ninu awọn ara Siria li ọjọ kan.

30. Sugbọn awọn iyokù salọ si Afeki, sinu ilu; odi si wolu ẹgbamẹtala-le-ẹgbẹrun ninu awọn enia ti o kù. Benhadadi si sa lọ, o si wá sinu ilu lati iyẹwu de iyẹwu.

31. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Kiyesi i, nisisiyi, awa ti gbọ́ pe, awọn ọba ile Israeli, alãnu ọba ni nwọn: mo bẹ ọ, jẹ ki awa ki o fi aṣọ-ọ̀fọ si ẹgbẹ wa, ati ijará yi ori wa ka, ki a si jade tọ̀ ọba Israeli lọ: bọya on o gba ẹmi rẹ là.

32. Bẹ̃ni nwọn di aṣọ ọ̀fọ mọ ẹgbẹ wọn, nwọn si fi ijara yi ori wọn ka, nwọn si tọ̀ ọba Israeli wá, nwọn si wipe, Benhadadi, iranṣẹ rẹ, wipe, Emi bẹ ọ, jẹ ki ẹmi mi ki o yè. On si wipe, O mbẹ lãye sibẹ? arakunrin mi li on iṣe.

33. Awọn ọkunrin na si ṣe akiyesi gidigidi, nwọn si yara gbá ohun ti o ti ọdọ rẹ̀ wá mu: nwọn si wipe, Benhadadi arakunrin rẹ! Nigbana li o wipe, Ẹ lọ mu u wá. Nigbana ni Benhadadi jade tọ̀ ọ wá; o si mu u goke wá sinu kẹkẹ́.

34. On si wi fun u pe, Awọn ilu ti baba mi gbà lọwọ baba rẹ, emi o mu wọn pada: iwọ o si là ọ̀na fun ara rẹ ni Damasku, bi baba mi ti ṣe ni Samaria. Nigbana ni Ahabu wipe, Emi o rán ọ lọ pẹlu majẹmu yi. Bẹ̃ li o ba a dá majẹmu, o si rán a lọ.

35. Ọkunrin kan ninu awọn ọmọ awọn woli si wi fun ẹnikeji rẹ̀ nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si kọ̀ lati lù u.