Yorùbá Bibeli

Joṣ 9:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ;

2. Nwọn si kó ara wọn jọ, lati fi ìmọ kan bá Joṣua ati Israeli jà.

3. Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai,

4. Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì;

5. Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi.

6. Nwọn si tọ̀ Joṣua lọ ni ibudó ni Gilgali, nwọn si wi fun u, ati fun awọn ọkunrin Israeli pe, Ilu òkere li awa ti wá; njẹ nitorina ẹ bá wa dá majẹmu.

7. Awọn ọkunrin Israeli si wi fun awọn Hifi pe, Bọya ẹnyin ngbé ãrin wa; awa o ti ṣe bá nyin dá majẹmu?

8. Nwọn si wi fun Joṣua pe, Iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Joṣua si wi fun wọn pe, Tali ẹnyin? nibo li ẹnyin si ti wá?

9. Nwọn si wi fun u pe, Ni ilu òkere rére li awọn iranṣẹ rẹ ti wá, nitori orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti awa ti gbọ́ okikí rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ṣe ni Egipti,

10. Ati ohun gbogbo ti o ṣe si awọn ọba awọn Amori meji, ti mbẹ ni òke Jordani, si Sihoni ọba Heṣboni, ati si Ogu ọba Baṣani, ti mbẹ ni Aṣtarotu.

11. Awọn àgba wa ati gbogbo awọn ara ilu wa sọ fun wa pe, Ẹ mú onjẹ li ọwọ́ nyin fun àjo na, ki ẹ si lọ ipade wọn, ki ẹ si wi fun wọn pe, Iranṣẹ nyin li awa iṣe: njẹ nitorina, ẹ bá wa dá majẹmu.

12. Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu:

13. Ìgo-awọ waini wọnyi, ti awa kún, titun ni nwọn; kiyesi i, nwọn fàya: ati ẹ̀wu wa wọnyi ati bàta wa di gbigbo nitori ọ̀na ti o jìn jù.