Yorùbá Bibeli

2. Sam 3:11-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. On kò si le da Abneri lohùn kan nitoriti o bẹ̀ru rẹ̀.

12. Abneri si ran awọn oniṣẹ si Dafidi nitori rẹ̀, wipe, Ti tani ilẹ na iṣe? ati pe, Ba mi ṣe adehun, si wõ, ọwọ́ mi o wà pẹlu rẹ, lati yi gbogbo Israeli sọdọ rẹ.

13. On si wi pe, O dara, emi o ba ọ ṣe adehun: ṣugbọn nkan kan li emi o bere lọwọ rẹ, eyini ni, Iwọ ki yio ri oju mi, afi bi iwọ ba mu Mikali ọmọbinrin Saulu wá, nigbati iwọ ba mbọ, lati ri oju mi.

14. Dafidi si ran awọn iranṣẹ si Iṣboṣeti ọmọ Saulu pe, Fi Mikali obinrin mi le mi lọwọ, ẹniti emi ti fi ọgọrun ẹfa abẹ awọn Filistini fẹ.

15. Iṣboṣeti si ranṣẹ, o si gbà a lọwọ ọkunrin ti a npè ni Faltieli ọmọ Laiṣi.

16. Ọkọ rẹ̀ si mba a lọ, o nrin, o si nsọkun lẹhin rẹ̀ titi o fi de Bahurimu. Abneri si wi fun u pe, Pada lọ. On si pada.

17. Abneri si ba awọn agbà Israeli sọ̀rọ, pe, Ẹnyin ti nṣe afẹri Dafidi ni igbà atijọ́, lati jọba lori nyin.

18. Njẹ, ẹ ṣe e: nitoriti Oluwa ti sọ fun Dafidi pe, Lati ọwọ́ Dafidi iranṣẹ mi li emi o gbà Israeli enia mi là kuro lọwọ awọn Filistini ati lọwọ gbogbo awọn ọta wọn.

19. Abneri si wi leti Benjamini: Abneri si lọ isọ leti Dafidi ni Hebroni gbogbo eyiti o dara loju Israeli, ati loju gbogbo ile Benjamini.

20. Abneri si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, ogún ọmọkunrin si pẹlu rẹ̀. Dafidi si se ase fun Abneri ati fun awọn ọmọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀.

21. Abneri si wi fun Dafidi pe, Emi o dide, emi o si lọ, emi o si ko gbogbo Israeli jọ sọdọ ọba oluwa mi, nwọn o si ba ọ ṣe adehun, iwọ o si jọba gbogbo wọn bi ọkàn rẹ ti nfẹ. Dafidi si rán Abneri lọ; on si lọ li alafia.

22. Si wõ, awọn iranṣẹ Dafidi ati Joabu si ti ibi ilepa ẹgbẹ ogun kan bọ̀, nwọn si mu ikogun pupọ bọ̀; ṣugbọn Abneri ko si lọdọ Dafidi ni Hebroni; nitoriti on ti rán a lọ: on si ti lọ li alafia.

23. Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia.

24. Joabu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Kini iwọ ṣe nì? wõ, Abneri tọ̀ ọ wá; ehatiṣe ti iwọ si fi rán a lọ? on si ti lọ.

25. Iwọ mọ̀ Abneri ọmọ Neri, pe, o wá lati tàn ọ jẹ, ati lati mọ̀ ijadelọ rẹ, ati ibọsile rẹ, ati lati mọ̀ gbogbo eyi ti iwọ nṣe.

26. Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀.