Yorùbá Bibeli

2. Sam 3:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OGUN na si pẹ titi larin idile Saulu ati idile Dafidi: agbara Dafidi si npọ̀ si i, ṣugbọn idile Saulu nrẹ̀hin si i.

2. Dafidi si bi ọmọkunrin ni Hebroni: Ammoni li akọbi rẹ̀ ti Ahinoamu ara Jesreeli bi fun u.

3. Ekeji rẹ̀ si ni Kileabu, ti Abigaili aya Nabali ara Karmeli nì bi fun u; ẹkẹta si ni Absalomu ọmọ ti Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Geṣuri bi fun u.

4. Ẹkẹrin si ni Adonija ọmọ Haggiti; ati ikarun ni Ṣefatia ọmọ Abitali;

5. Ẹkẹfa si ni Itreamu, ti Egla aya Dafidi bi fun u. Wọnyi li a bi fun Dafidi ni Hebroni.

6. O si ṣe, nigbati ogun wà larin idile Saulu ati idile Dafidi, Abneri si di alagbara ni idile Saulu.

7. Saulu ti ni àle kan, orukọ rẹ̀ si njẹ Rispa, ọmọbinrin Aia: Iṣboṣeti si bi Abneri lere pe, Ẽṣe ti iwọ fi wọle tọ àle baba mi lọ?

8. Abneri si binu gidigidi nitori ọ̀rọ wọnyi ti Iṣboṣeti sọ fun u, o si wipe, Emi iṣe ori aja bi? emi ti mo mba Juda jà, ti mo si ṣanu loni fun idile Saulu baba rẹ, ati fun ará rẹ̀, ati awọn ọrẹ rẹ̀, ti emi kò si fi iwọ le Dafidi lọwọ, iwọ si ka ẹ̀ṣẹ si mi lọrùn nitori obinrin yi loni?

9. Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si Abneri, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi Oluwa ti bura fun Dafidi, bi emi kò ni ṣe bẹ fun u.

10. Lati mu ijọba na kuro ni idile Saulu, ati lati gbe itẹ Dafidi kalẹ lori Israeli, ati lori Juda, lati Dani titi o fi de Beerṣeba.

11. On kò si le da Abneri lohùn kan nitoriti o bẹ̀ru rẹ̀.

12. Abneri si ran awọn oniṣẹ si Dafidi nitori rẹ̀, wipe, Ti tani ilẹ na iṣe? ati pe, Ba mi ṣe adehun, si wõ, ọwọ́ mi o wà pẹlu rẹ, lati yi gbogbo Israeli sọdọ rẹ.

13. On si wi pe, O dara, emi o ba ọ ṣe adehun: ṣugbọn nkan kan li emi o bere lọwọ rẹ, eyini ni, Iwọ ki yio ri oju mi, afi bi iwọ ba mu Mikali ọmọbinrin Saulu wá, nigbati iwọ ba mbọ, lati ri oju mi.

14. Dafidi si ran awọn iranṣẹ si Iṣboṣeti ọmọ Saulu pe, Fi Mikali obinrin mi le mi lọwọ, ẹniti emi ti fi ọgọrun ẹfa abẹ awọn Filistini fẹ.

15. Iṣboṣeti si ranṣẹ, o si gbà a lọwọ ọkunrin ti a npè ni Faltieli ọmọ Laiṣi.

16. Ọkọ rẹ̀ si mba a lọ, o nrin, o si nsọkun lẹhin rẹ̀ titi o fi de Bahurimu. Abneri si wi fun u pe, Pada lọ. On si pada.

17. Abneri si ba awọn agbà Israeli sọ̀rọ, pe, Ẹnyin ti nṣe afẹri Dafidi ni igbà atijọ́, lati jọba lori nyin.

18. Njẹ, ẹ ṣe e: nitoriti Oluwa ti sọ fun Dafidi pe, Lati ọwọ́ Dafidi iranṣẹ mi li emi o gbà Israeli enia mi là kuro lọwọ awọn Filistini ati lọwọ gbogbo awọn ọta wọn.