Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 8:20-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Li ọjọ rẹ̀ ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro li abẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn.

21. Bẹ̃ni Joramu rekọja siha Sairi, ati gbogbo awọn kẹkẹ́ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o yi i ka: ati awọn olori awọn kẹkẹ́: awọn enia si sá wọ inu agọ wọn.

22. Bẹ̃ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda titi o fi di oni yi. Nigbana ni Libna ṣọ̀tẹ li akokò kanna.

23. Iyokù iṣe Joramu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

24. Joramu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Ahasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

25. Li ọdun kejila Joramu ọmọ Ahabu ọba Israeli, Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

26. Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Ataliah, ọmọbinrin Omri ọba Israeli.

27. O si rìn li ọ̀na ile Ahabu, o si ṣe ibi niwaju Oluwa, bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o nṣe ana ile Ahabu.

28. On si lọ pẹlu Joramu ọmọ Ahabu si ogun na ti o mba Hasaeli ọba Siria jà ni Ramoti-Gileadi; awọn ara Siria si ṣa Joramu li ọgbẹ́.

29. Joramu ọba si pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ti ṣa a ni Rama, nigbati o mba Hasaeli ọba Siria ja. Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu ọmọ Ahabu ni Jesreeli nitoriti o nṣe aisàn.