Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 7:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Eliṣa wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Bayi li Oluwa wi, Ni iwòyi ọla li a o ta oṣùwọn iyẹ̀fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria.

2. Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ sé ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.

3. Adẹtẹ̀ mẹrin kan si wà ni atiwọ̀ bodè; nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú?

4. Bi awa ba wipe, Awa o wọ̀ ilu lọ, iyàn si mbẹ ni ilu, awa o si kú nibẹ: bi awa ba si joko jẹ nihinyi, awa o kú pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki awa ki o ṣubu si ọwọ ogun awọn ara Siria: bi nwọn ba dá wa si, awa o yè: bi nwọn ba si pa wa, awa o kú na ni.

5. Nwọn si dide li afẹ̀mọjumọ lati lọ si ibùdo awọn ara Siria: nigbati nwọn si de apa ti o kangun ibùdo Siria, kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ.

6. Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ.