Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ.