Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 5:23-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Naamani si wipe, Fi ara balẹ, gbà talenti meji. O si rọ̀ ọ, o si dì talenti fadakà meji sinu apò meji, pẹlu ipàrọ aṣọ meji, o si gbé wọn rù ọmọ-ọdọ rẹ̀ meji; nwọn si rù wọn niwaju rẹ̀.

24. Nigbati o si de ibi ile ìṣọ, o gbà wọn lọwọ wọn, o si tò wọn sinu ile: o si jọ̀wọ awọn ọkunrin na lọwọ lọ, nwọn si jade lọ.

25. Ṣugbọn on wọ̀ inu ile lọ, o si duro niwaju oluwa rẹ̀. Eliṣa si wi fun u pe, Gehasi, nibo ni iwọ ti mbọ̀? On si wipe, Iranṣẹ rẹ kò lọ ibikibi.

26. On si wi fun u pe, Ọkàn mi kò ha ba ọ lọ, nigbati ọkunrin na fi yipada kuro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ lati pade rẹ? Eyi ha iṣe akokò ati gbà fadakà, ati lati gbà aṣọ, ati ọgbà-olifi ati ọgbà-ajara, ati àgutan, ati malu, ati iranṣékunrin ati iranṣẹbinrin?

27. Nitorina ẹ̀tẹ Naamani yio lẹ mọ ọ, ati iru-ọmọ rẹ titi lai. On si jade kuro niwaju rẹ̀, li adẹtẹ̀ ti o funfun bi ojodidì.