Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 4:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbana li o wá, o si sọ fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Lọ, tà ororo na, ki o si san gbèse rẹ, ki iwọ ati awọn ọmọ rẹ ki o si jẹ eyi ti o kù.

8. O si di ọjọ kan, Eliṣa si kọja si Ṣunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wà; on si rọ̀ ọ lati jẹ onjẹ. O si ṣe, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a yà si ibẹ lati jẹ onjẹ.

9. On si wi fun ọkọ rẹ̀ pe, Sa wò o na, emi woye pe, enia mimọ́ Ọlọrun li eyi ti ngbà ọdọ wa kọja nigbakugba.

10. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a ṣe yàrá kekere kan lara ogiri; si jẹ ki a gbe ibùsùn kan sibẹ fun u, ati tabili kan, ati ohun-ijoko kan, ati ọpá-fitila kan: yio si ṣe, nigbati o ba tọ̀ wa wá, ki on ma wọ̀ sibẹ.

11. O si di ọjọ kan, ti o wá ibẹ̀, o si yà sinu yàrá na, o si dubulẹ nibẹ.

12. On si wi fun Gehasi iranṣẹ rẹ̀ pe, Pè ara Ṣunemu yi. Nigbati o si pè e, o duro niwaju rẹ̀.

13. On si wi fun u pe, nisisiyi, sọ fun u pe, Kiyesi i, iwọ ti fi gbogbo itọju yi ṣe aniyàn wa; kini a ba ṣe fun ọ? Iwọ nfẹ́ ki a sọ̀rọ rẹ fun ọba bi? tabi fun olori-ogun? On si dahùn wipe, Emi ngbe lãrin awọn enia mi.

14. On si wipe, Njẹ kini a ba ṣe fun u? Gehasi si dahùn pe, Nitõtọ, on kò li ọmọ, ọkọ rẹ̀ si di arugbo.

15. On si wipe, Pè e wá, nigbati o si ti pè e de, o duro li ẹnu-ọ̀na.

16. On si wipe, Li akokò yi gẹgẹ bi igba aiye, iwọ gbé ọmọkunrin kan mọra. On si wipe, Bẹ̃kọ̀, oluwa mi, iwọ enia Ọlọrun, má ṣe purọ fun iranṣẹbinrin rẹ.

17. Obinrin na si loyun, o si bi ọmọkunrin kan li akokò na ti Eliṣa ti sọ fun u, gẹgẹ bi igba aiye.

18. Nigbati ọmọ na si dagba, o di ọjọ kan, ti o jade tọ̀ baba rẹ̀ lọ si ọdọ awọn olukore.

19. O si wi fun baba rẹ̀ pe, Ori mi, ori mi! On si sọ fun ọmọ-ọdọ̀ kan pe, Gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ.

20. Nigbati o si gbé e, ti o mu u tọ̀ iya rẹ̀ wá, o joko li ẽkun rẹ̀ titi di ọjọ kanri, o si kú.