Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 3:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ṣugbọn o fi ara mọ ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ; kò si lọ kuro ninu rẹ̀.

4. Meṣa, ọba Moabu si nsìn agutan, o si nsan ọkẹ marun ọdọ-agutan, ati ọkẹ marun àgbo irun fun ọba Israeli.

5. O si ṣe, nigbati Ahabu kú, ọba Moabu si ṣọ̀tẹ si ọba Israeli.

6. Jehoramu ọba si jade lọ kuro ni Samaria li akoko na, o si ka iye gbogbo Israeli.

7. O si lọ, o ranṣẹ si Jehoṣafati ọba Juda, wipe, Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ si mi: iwọ o ha bá mi lọ si Moabu lati jagun? On si wipe, Emi o gòke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.

8. On si wipe, Ọ̀na wo li awa o gbà gòke lọ? On si dahùn wipe, Ọ̀na aginju Edomu.

9. Bẹ̃ni ọba Israeli lọ, ati ọba Juda, ati ọba Edomu: nigbati nwọn rìn àrinyika ijọ meje, omi kò si si nibẹ fun awọn ogun, ati fun ẹranko ti ntọ̀ wọn lẹhin.

10. Ọba Israeli si wipe, O ṣe! ti Oluwa fi pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ!

11. Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi.

12. Jehoṣafati si wipe, Ọ̀rọ Oluwa mbẹ pẹlu rẹ̀. Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati ati ọba Edomu sọ̀kalẹ tọ̀ ọ lọ.

13. Eliṣa si wi fun ọba Israeli pe, Kini o ṣe mi ṣe ọ? Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃kọ: nitori ti Oluwa ti pè awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ.

14. Eliṣa si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, iba má ṣepe mo bu ọwọ Jehoṣafati ọba Juda, nitõtọ emi kì ba ti bẹ̀ ọ wò, bẹ̃ni emi kì ba ti ri ọ.