Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 24:15-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. O si mu Jehoiakini lọ si Babeli, ati iya ọba, ati awọn obinrin ọba, ati awọn iwẹ̀fa rẹ̀, ati awọn alagbara ilẹ na, awọn wọnyi li o kó ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli.

16. Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọla, ẹ̃dẹgbãrin, ati awọn oniṣọnà ati awọn alagbẹdẹ ẹgbẹrun, gbogbo awọn ti o li agbara ti o si yẹ fun ogun, ani awọn li ọba Babeli kó ni igbèkun lọ si Babeli.

17. Ọba Babeli si fi Mattaniah arakunrin baba rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Sedekiah.

18. Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna.

19. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.

20. Nitori nipa ibinu Oluwa li o ṣẹ si Jerusalemu ati Juda, titi o fi ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀; Sedekiah si ṣọ̀tẹ si ọba Babeli.