Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 23:16-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bi Josiah si ti yira pada, o ri awọn isà-okú ti o wà lori òke, o si ranṣẹ, o si kó awọn egungun lati inu isà wọnni kuro, o si sun wọn lori pẹpẹ na, o si sọ ọ di ẽri, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti enia Ọlọrun nì ti kede, ẹniti o kede ọ̀ro wọnyi.

17. Nigbana li o wipe, Ọwọ̀n isa-okú wo li eyi ti mo ri nì? Awọn enia ilu na si sọ fun u pe, Isà-okú enia Ọlọrun nì ni, ti o ti Juda wá, ti o si kede nkan wọnyi ti iwọ ti ṣe si pẹpẹ Beteli.

18. On si wipe, Jọwọ rẹ̀; máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mu egungun rẹ̀ kuro. Bẹ̃ni nwọn jọwọ egungun rẹ̀ lọwọ, pẹlu egungun woli ti o ti Samaria wá.

19. Ati pẹlu gbogbo ile ibi-giga wọnni ti o wà ni ilu Samaria wọnni, ti awọn ọba Israeli ti kọ́ lati rú ibinu Oluwa soke ni Josiah mu kuro, o si ṣe si wọn gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti o ṣe ni Beteli.

20. O si pa gbogbo awọn alufa ibi-giga wọnni ti o wà nibẹ lori awọn pẹpẹ na, o si sun egungun enia lori wọn, o si pada si Jerusalemu.

21. Ọba si paṣẹ fun gbogbo enia, wipe, Pa irekọja mọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin, bi a ti kọ ọ ninu iwe majẹmu yi.

22. Nitõtọ a kò ṣe iru irekọja bẹ̃ lati ọjọ awọn onidajọ ti ndajọ ni Israeli, tabi ni gbogbo ọjọ awọn ọba Israeli tabi awọn ọba Juda;

23. Ṣugbọn li ọdun kejidilogun Josiah ọba, ni a pa irekọja yi mọ́ fun Oluwa ni Jerusalemu.

24. Ati pẹlu awọn ti mba awọn okú lò, ati awọn oṣo, ati awọn ere, ati awọn oriṣa, ati gbogbo irira ti a ri ni ilẹ Juda ati ni Jerusalemu ni Josiah kó kuro, ki o le mu ọ̀rọ ofin na ṣẹ ti a ti kọ sinu iwe ti Hilkiah alufa ri ni ile Oluwa.