Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 18:9-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O si ṣe li ọdun kẹrin Hesekiah ọba, ti iṣe ọdun keje Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli, ni Ṣalmaneseri ọba Assiria gòke wá si Samaria, o si dotì i.

10. Lẹhin ọdun mẹta nwọn kó o; ani li ọdun kẹfa Hesekiah, eyini ni ọdun kẹsan Hoṣea ọba Israeli li a kó Samaria.

11. Ọba Assiria si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori leti odò Gosani, ati si ilẹ awọn ara Media wọnni:

12. Nitoriti nwọn kò gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ṣugbọn nwọn dà majẹmu rẹ̀, ati ohun gbogbo ti Mose iranṣẹ Oluwa pa li aṣẹ, nwọn kò si fi eti si wọn, bẹ̃ni nwọn kò si ṣe wọn.

13. Li ọdun kẹrinla Hesekiah ọba, ni Sennakeribu ọba Assiria gòke wá si gbogbo awọn ilu olodi Juda, o si kó wọn.

14. Hesekiah ọba Juda si ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wipe, Mo ti ṣẹ̀; padà lẹhin mi: eyiti iwọ ba bù fun mi li emi o rù. Ọba Assiria si bù ọ̃dunrun talenti fadakà, ati ọgbọ̀n talenti wura fun Hesekiah ọba Juda.