Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 17:24-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ọba Assiria si kó enia lati Babeli wá, ati lati Kuta, ati lati Afa, ati lati Hamati, ati lati Sefarfaimi, o si fi wọn sinu ilu Samaria wọnni, ni ipò awọn ọmọ Israeli; nwọn si ni Samaria, nwọn si ngbe inu rẹ̀ wọnni.

25. O si ṣe li atètekọ-gbé ibẹ wọn, nwọn kò bẹ̀ru Oluwa: nitorina ni Oluwa ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, ti o pa ninu wọn.

26. Nitorina ni nwọn ṣe sọ fun ọba Assiria wipe, Awọn orilẹ-ède ti iwọ ṣi kuro, ti o si fi sinu ilu Samaria wọnni, kò mọ̀ iṣe Ọ̀lọrun ilẹ na: nitorina li on ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, si kiyesi i, nwọn pa wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ iṣe Ọlọrun ilẹ na.

27. Nigbana li ọba Assiria paṣẹ, wipe, Ẹ mu ọkan ninu awọn alufa ti ẹnyin ti kó ti ọhún wá lọ sibẹ; ẹ si jẹ ki wọn ki o lọ igbe ibẹ, ki ẹ si jẹ ki o ma kọ́ wọn ni iṣe Ọlọrun ilẹ na.

28. Nigbana ni ọkan ninu awọn alufa ti nwọn ti kó ti Samaria lọ, wá, o si joko ni Beteli, o si kọ́ wọn bi nwọn o ti mã bẹ̀ru Oluwa.

29. Ṣugbọn olukuluku orilẹ-ède ṣe oriṣa tirẹ̀, nwọn si fi wọn sinu ile ibi giga wọnni ti awọn ara Samaria ti ṣe, olukuluku orilẹ-ède ninu ilu ti nwọn ngbe.

30. Awọn enia Babeli ṣe agọ awọn wundia, ati awọn enia Kuti ṣe oriṣa Nergali, ati awọn enia Hamati ṣe ti Aṣima,

31. Ati awọn ara Afa ṣe ti Nibhasi ati ti Tartaki, ati awọn ara Sefarfaimu sun awọn ọmọ wọn ninu iná fun Adrammeleki ati Anammeleki awọn òriṣa Sefarfaimu.

32. Nwọn bẹ̀ru Oluwa pẹlu, nwọn si ṣe alufa ibi giga wọnni fun ara wọn, ninu awọn enia lasan, ti nrubọ fun wọn ni ile ibi giga wọnni.

33. Nwọn bẹ̀ru Oluwa, nwọn si nsìn oriṣa wọn gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède, ti nwọn kó lati ibẹ lọ.