Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 16:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbana ni Resini ọba Siria ati Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli gòke wá si Jerusalemu lati jagun: nwọn si do tì Ahasi, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.

6. Li akokò na, Resini ọba Siria gbà Elati pada fun Siria, o si lé awọn enia Juda kuro ni Elati: awọn ara Siria si wá si Elati, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.

7. Ahasi si rán onṣẹ si ọdọ Tiglat-pileseri ọba Assiria wipe, Iranṣẹ rẹ li emi, ati ọmọ rẹ; gòke wá, ki o si gbà mi lọwọ ọba Siria, ati lọwọ ọba Israeli, ti o dide si mi.

8. Ahasi si mu fadakà ati wura ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, o si rán a li ọrẹ si ọba Assiria.

9. Ọba Assiria si gbọ́ tirẹ̀: nitoriti ọba Assiria gòke wá si Damasku, o si kó o, o si mu u ni igbèkun lọ si Kiri, o si pa Resini.

10. Ahasi ọba si lọ si Damasku lati pade Tiglat-pileseri, ọba Assiria, o si ri pẹpẹ kan ti o wà ni Damasku: Ahasi ọba si rán awòran pẹpẹ na, ati apẹrẹ rẹ̀ si Urijah alufa, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ ọnà rẹ̀.