Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 12:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.

8. Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe.

9. Ṣugbọn Jehoiada alufa mu apoti kan, o si dá ideri rẹ̀ lu, o si fi i si ẹba pẹpẹ na, li apa ọtún bi ẹnikan ti nwọ̀ inu ile Oluwa lọ: awọn alufa ti o si ntọju iloro na fi gbogbo owo ti a mu wá inu ile Oluwa sinu rẹ̀.

10. O si ṣe, nigbati nwọn ri pe, owo pupọ̀ mbẹ ninu apoti na, ni akọwe ọba, ati olori alufa gòke wá, nwọn si dì i sinu apò, nwọn si kà iye owo ti a ri ninu ile Oluwa.

11. Nwọn si fi owo na ti a kà le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, awọn ti o nṣe abojuto ile Oluwa: nwọn si ná a fun awọn gbẹnagbẹna, ati awọn akọle, ti nṣiṣẹ ile Oluwa.

12. Ati fun awọn ọmọle, ati awọn agbẹ́kuta, ati lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tun ẹya ile Oluwa ṣe, ati fun gbogbo eyi ti a ná fun ile na lati tun u ṣe.

13. Ṣugbọn ninu owo ti a mu wá sinu ile Oluwa, a kò fi ṣe ọpọ́n fadakà, alumagàji fitila, awokoto, ipè ohun èlo wura tabi ohun elò fadakà kan fun ile Oluwa:

14. Ṣugbọn nwọn fi i fun awọn ti nṣiṣe na, nwọn si fi tun ile Oluwa ṣe.

15. Nwọn kò si ba awọn ọkunrin na ṣirò, li ọwọ ẹniti nwọn fi owo na le, lati fi fun awọn ti nṣiṣẹ; nitoriti nwọn ṣe otitọ.

16. Owo ẹbọ irekọja ati owo ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni a kò mu wá sinu ile Oluwa: ti awọn alufa ni.