Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 10:28-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israeli.

29. Ṣugbọn Jehu kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o mu Israeli ṣẹ̀, eyinì ni, awọn ẹgbọ̀rọ malu wura ti o wà ni Beteli, ati eyiti o wà ni Dani.

30. Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli.

31. Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀.

32. Li ọjọ wọnni Oluwa bẹ̀rẹ si iké Israeli kuru: Hasaeli si kọlù wọn ni gbogbo agbègbe Israeli;

33. Lati Jordani nihà ilà-õrùn, gbogbo ilẹ Gileadi, awọn enia Gadi, ati awọn enia Reubeni, ati awọn enia Manasse, lati Aroeri, ti o wà leti odò Arnoni, ani Gileadi ati Baṣani.

34. Ati iyokù iṣe Jehu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati gbogbo agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

35. Jehu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: nwọn si sìn i ni Samaria. Jehoahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

36. Ọjọ ti Jehu jọba lori Israeli ni Samaria sì jẹ ọdun mejidilọgbọ̀n.