Lati Jordani nihà ilà-õrùn, gbogbo ilẹ Gileadi, awọn enia Gadi, ati awọn enia Reubeni, ati awọn enia Manasse, lati Aroeri, ti o wà leti odò Arnoni, ani Gileadi ati Baṣani.