Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 8:57-66 Yorùbá Bibeli (YCE)

57. Oluwa Ọlọrun wa ki o wà pẹlu wa, bi o ti wà pẹlu awọn baba wa: ki o má fi wa silẹ, ki o má si ṣe kọ̀ wa silẹ;

58. Ṣugbọn ki o fa ọkàn wa si ọdọ ara rẹ̀, lati ma rin ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ti o ti paṣẹ fun awọn baba wa.

59. Ki o si jẹ ki ọ̀rọ mi wọnyi, ti mo fi bẹ̀bẹ niwaju Oluwa, ki o wà nitosi, Oluwa Ọlọrun wa, li ọsan ati li oru, ki o le mu ọ̀ran iranṣẹ rẹ duro, ati ọ̀ran ojojumọ ti Israeli, enia rẹ̀.

60. Ki gbogbo enia aiye le mọ̀ pe, Oluwa on li Ọlọrun, kò si ẹlomiran.

61. Nitorina, ẹ jẹ ki aìya nyin ki o pé pẹlu Oluwa Ọlọrun wa, lati mã rìn ninu aṣẹ rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, bi ti oni yi.

62. Ati ọba, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ru ẹbọ niwaju Oluwa.

63. Solomoni si ru ẹbọ ọrẹ-alafia, ti o ru si Oluwa, ẹgbã-mọkanla malu, ati ọkẹ mẹfa àgutan. Bẹ̃ni ọba ati gbogbo awọn ọmọ Israeli yà ile Oluwa si mimọ́.

64. Li ọ̀jọ na ni ọba yà agbàla ãrin ti mbẹ niwaju ile Oluwa si mimọ́: nitori nibẹ ni o ru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ọrẹ-onjẹ, ati ẹbọ-ọpẹ: nitori pẹpẹ idẹ ti mbẹ niwaju Oluwa kere jù lati gba ọrẹ-sisun ati ọrẹ-ọnjẹ, ati ọ̀ra ẹbọ-ọpẹ.

65. Ati li àkoko na, Solomoni papejọ kan, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ajọ nla-nlã ni, lati iwọ Hamati titi de odò Egipti, niwaju Oluwa Ọlọrun wa, ijọ meje on ijọ meje, ani ijọ mẹrinla.

66. Li ọjọ kẹjọ o rán awọn enia na lọ: nwọn si sure fun ọba, nwọn si lọ sinu agọ wọn pẹlu ayọ̀ ati inu-didun, nitori gbogbo ore ti Oluwa ti ṣe fun Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fun Israeli, enia rẹ̀.