Ki o si jẹ ki ọ̀rọ mi wọnyi, ti mo fi bẹ̀bẹ niwaju Oluwa, ki o wà nitosi, Oluwa Ọlọrun wa, li ọsan ati li oru, ki o le mu ọ̀ran iranṣẹ rẹ duro, ati ọ̀ran ojojumọ ti Israeli, enia rẹ̀.